2Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò, ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàn a kò fi idà pa àwọn òkú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun.
3Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ; a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà. Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀, lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà lọ́nà jíjìn réré.
4Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi: jẹ́ kí n sọkún kíkorò. Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”
5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan tí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ní àfonífojì ìmọ̀, ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀ àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.
6Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin, Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.