Isaiah 23

Láti orí àwọn omi ńlá ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá; ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire, òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè.

Isaiah 23:3 (UKJV) And by great waters the seed of Sihor, the harvest of the river, is her revenue; and she is a merchant of nations.

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire. Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi! Nítorí a ti pa Tire run láìsí ilé tàbí èbúté. Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

2Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni, ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀.

3Láti orí àwọn omi ńlá ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá; ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire, òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè.

4Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun, nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀. “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”

5Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti, wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti Tire.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.