Isaiah 27

Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì gẹ́gẹ́ bí aginjù; níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀; wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.

Isaiah 27:10 (UKJV) Yet the defenced city shall be desolate, and the habitation forsaken, and left like a wilderness: there shall the calf feed, and there shall he lie down, and consume the branches thereof.

8Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó fi dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́.

9Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró.

10Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì gẹ́gẹ́ bí aginjù; níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀; wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.

11Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́, nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn; bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.

12Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.