Isaiah 29

Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.

Isaiah 29:23 (UKJV) But when he sees his children, the work of mine hands, in the midst of him, they shall sanctify my name, and sanctify the Holy One of Jacob, and shall fear the God of Israel.

21àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi, ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́ tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.

22Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu: “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́; ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.

23Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.

24Gbogbo àwọn tí ń rìn ségesège ní yóò jèrè ìmọ̀; gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.