Isaiah 41

“Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí. “Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí,

Isaiah 41:21 (UKJV) Produce your cause, says the LORD; bring forth your strong reasons, says the King of Jacob.

19Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀ igi kedari àti kasia, maritili àti olifi. Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù, igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀

20tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí, àti pé, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.

21“Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí. “Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí,

22“Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́, kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn kí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí. Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá,

23ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání kí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín. Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú, tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.