Isaiah 41

tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí, àti pé, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.

Isaiah 41:20 (UKJV) That they may see, and know, and consider, and understand together, that the hand of the LORD has done this, and the Holy One of Israel has created it.

18Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga àti orísun omi ní àárín àfonífojì. Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi.

19Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀ igi kedari àti kasia, maritili àti olifi. Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù, igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀

20tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí, àti pé, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.

21“Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí. “Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí,

22“Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́, kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn kí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí. Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.