Isaiah 45

Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì wọn yóò sì kan àbùkù; gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.

Isaiah 45:16 (UKJV) They shall be ashamed, and also confounded, all of them: they shall go to confusion together that are makers of idols.

14Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi, àti àwọn Sabeani— wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ; wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn, wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀, wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé, ‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn; kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

15Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́, Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli,

16Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì wọn yóò sì kan àbùkù; gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.

17Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé; a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín, títí ayé àìnípẹ̀kun.

18Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀, Òun wí pé: “Èmi ni Olúwa, kò sì ṣí ẹlòmíràn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.