Isaiah 45

Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀, Òun wí pé: “Èmi ni Olúwa, kò sì ṣí ẹlòmíràn.

Isaiah 45:18 (UKJV) For thus says the LORD that created the heavens; God himself that formed the earth and made it; he has established it, he created it not in vain, he formed it to be inhabited: I am the LORD; and there is none else.

16Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì wọn yóò sì kan àbùkù; gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.

17Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé; a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín, títí ayé àìnípẹ̀kun.

18Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀, Òun wí pé: “Èmi ni Olúwa, kò sì ṣí ẹlòmíràn.

19Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin, láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn, Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé, ‘Ẹ wá mi lórí asán.’ Èmi Olúwa sọ òtítọ́, Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.

20“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá; ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá. Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri, tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.