Isaiah 47

“Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúńdíá ọmọbìnrin Babeli; jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli. A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.

Isaiah 47:1 (UKJV) Come down, and sit in the dust, O virgin daughter of Babylon, sit on the ground: there is no throne, O daughter of the Chaldeans: for you shall no more be called tender and delicate.

1“Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúńdíá ọmọbìnrin Babeli; jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli. A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.

2Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun; mú ìbòjú rẹ kúrò. Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan, kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá.

3Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀san, Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.