Isaiah 47

Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

Isaiah 47:4 (UKJV) As for our redeemer, the LORD of hosts is his name, the Holy One of Israel.

2Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun; mú ìbòjú rẹ kúrò. Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan, kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá.

3Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀san, Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”

4Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

5“Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli; a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin àwọn ilẹ̀ ọba mọ́.

6Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́, mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n. Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.