Isaiah 56

Èyí ni ohun ti Olúwa sọ: “Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà, nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.

Isaiah 56:1 (UKJV) Thus says the LORD, Keep all of you judgment, and do justice: for my salvation is near to come, and my righteousness to be revealed.

1Èyí ni ohun ti Olúwa sọ: “Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà, nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.

2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí, àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin, tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

3Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ Olúwa sọ wí pé, “Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé, “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.