13Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín! Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ, èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ náà yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”
14A ó sì sọ wí pé: “Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe! Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
15Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
16Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé, tàbí kí n máa bínú sá á, nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi èémí ènìyàn tí mo ti dá.
17Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú; síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.