17Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú; síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn; Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli. Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,” ni Olúwa wí, “Àti pé, Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun tí kò le è sinmi, tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
21“Kò sí àlàáfíà fún àwọn ìkà,” ni Ọlọ́run mi wí.