Isaiah 60

A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́, tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn.

Isaiah 60:18 (UKJV) Violence shall no more be heard in your land, wasting nor destruction within your borders; but you shall call your walls Salvation, and your gates Praise.

16Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.

17Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ, dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ, àti irin dípò òkúta. Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.

18A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́, tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn.

19Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.

20Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́, àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́; Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ, àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.