1“Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.
2Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́ ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.
3Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ, àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.
4“Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò. Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ; àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.