12Àwọn ìlú Juda àti àwọn ará Jerusalẹmu yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́njú náà bá dé.
13Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’
14“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú.
15“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi, bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè? Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀? Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀, nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.”
16Olúwa pè ọ́ ní igi olifi pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.