Jeremiah 13

Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá. Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà; àgùntàn tí ò ń mú yangàn.

Jeremiah 13:20 (UKJV) Lift up your eyes, and behold them that come from the north: where is the flock that was given you, your beautiful flock?

18Sọ fún ọba àti ayaba pé, “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín, adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”

19Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn. Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.

20Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá. Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà; àgùntàn tí ò ń mú yangàn.

21Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí?

22Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀ ni aṣọ rẹ fi fàya tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.