Jeremiah 13

Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn. Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.

Jeremiah 13:19 (UKJV) The cities of the south shall be shut up, and none shall open them: Judah shall be carried away captive all of it, it shall be wholly carried away captive.

17Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀, Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín. Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò, tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde, nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

18Sọ fún ọba àti ayaba pé, “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín, adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”

19Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn. Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.

20Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá. Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà; àgùntàn tí ò ń mú yangàn.

21Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.