Jeremiah 13

Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí?

Jeremiah 13:21 (UKJV) What will you say when he shall punish you? for you have taught them to be captains, and as chief over you: shall not sorrows take you, as a woman in travail?

19Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn. Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.

20Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá. Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà; àgùntàn tí ò ń mú yangàn.

21Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí?

22Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀ ni aṣọ rẹ fi fàya tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe.

23Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà? Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà? Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.