Jeremiah 22

Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi, gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni, dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.

Jeremiah 22:6 (UKJV) For thus says the LORD unto the king's house of Judah; You are Gilead unto me, and the head of Lebanon: yet surely I will make you a wilderness, and cities which are not inhabited.

4Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba inú ààfin láti ẹnu-ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn.

5Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”

6Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi, gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni, dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.

7Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀, wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀, wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.

8“Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.