2“Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́? Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́, bí i ará Arabia kan nínú aginjù, ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́ pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ.
3Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn, kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò. Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà, ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú.
4Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé, ‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
5Ìwọ yóò ha máa bínú títí? Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’ Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀ ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.”
6Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.