Jeremiah 30

‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’ ”

Jeremiah 30:22 (UKJV) And all of you shall be my people, and I will be your God.

20Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí. Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára, ni èmi yóò fì ìyà jẹ.

21Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn, ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn. Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi, nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’ ni Olúwa wí.

22‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’ ”

23Wò ó, ìbínú Olúwa yóò tú jáde, ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.

24Ìbínú ńlá Olúwa kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ìkà títí yóò fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ. Ní àìpẹ́ ọjọ́, òye rẹ̀ yóò yé e yín.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.