4Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda:
5“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́ láìṣe igbe àlàáfíà.
6Béèrè kí o sì rí. Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí? Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí, tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?
7Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó! Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀, Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.
8“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù. Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́.