Jeremiah 30

“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù. Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́.

Jeremiah 30:8 (UKJV) For it shall come to pass in that day, says the LORD of hosts, that I will break his yoke from off your neck, and will burst your bonds, and strangers shall no more make use of him:

6Béèrè kí o sì rí. Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí? Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí, tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?

7Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó! Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀, Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.

8“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù. Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́.

9Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn, ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.

10“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.