29“A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu: àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀ àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.
30Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,” ni Olúwa wí, “ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan.
31Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí Moabu fún àwọn ará Moabu ni mo kígbe lóhùn rara, mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.
32Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkún ìwọ àjàrà Sibma. Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun, wọn dé Òkun Jaseri. Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ, ìkórè èso àjàrà rẹ.
33Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò nínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu. Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí; kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà, wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀.