Jeremiah 49

Nípa Ammoni. Báyìí ni Olúwa wí, “Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin? Israẹli kò ha ní àrólé bí? Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?

Jeremiah 49:1 (UKJV) Concerning the Ammonites, thus says the LORD; Has Israel no sons? has he no heir? why then does their king inherit Gad, and his people dwell in his cities?

1Nípa Ammoni. Báyìí ni Olúwa wí, “Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin? Israẹli kò ha ní àrólé bí? Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?

2Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí; “nígbà tí èmi yóò mú kí a gbọ́ ìdágìrì ogun ní Rabba tí Ammoni; yóò sì di òkìtì ahoro, gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná. Nígbà náà ni Israẹli yóò lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,” ni Olúwa wí.

3“Hu, ìwọ Heṣboni, nítorí Ai tí rún! Kígbe ẹ̀yin olùgbé Rabba! Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà, nítorí Malkomu yóò lọ sí ìgbèkùn, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.