17“Edomu yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ.
18Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní Olúwa wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.
19“Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
20Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí Olúwa ní fún Edomu, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani. Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde; pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.
21Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn, a ó gbọ́ igbe wọn ní Òkun pupa.