22Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀, yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí.
23Nípa Damasku. “Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn, wọ́n sì dààmú bí omi Òkun.
24Damasku di aláìlera, ó pẹ̀yìndà láti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a; ìbẹ̀rù àti ìrora dìímú, ìrora bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.
25Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀; ìlú tí mo dunnú sí.
26Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.