Jeremiah 51

Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀, àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí.

Jeremiah 51:28 (UKJV) Prepare against her the nations with the kings of the Medes, the captains thereof, and all the rulers thereof, and all the land of his dominion.

26A kò ní mú òkúta kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di ahoro títí ayé,” ní Olúwa wí.

27“Gbé àsíá sókè ní ilẹ̀ náà! Fọn ìpè láàrín àwọn orílẹ̀-èdè! Sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ sórí rẹ̀, pe àwọn ìjọba yìí láti dojúkọ ọ́: Ararati, Minini àti Aṣkenasi. Yan olùdarí ogun láti kọlù ú, rán àwọn ẹṣin sí i bí ọ̀pọ̀ eṣú.

28Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀, àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí.

29Ilẹ̀ wárìrì síyìn-ín sọ́hùn-ún, nítorí pé ète Olúwa, sí Babeli dúró, láti ba ilẹ̀ Babeli jẹ́ lọ́nà tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́.

30Gbogbo àwọn jagunjagun Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn. Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin. Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun, gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.