Jeremiah 51

Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́ ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”

Jeremiah 51:32 (UKJV) And that the passages are stopped, and the reeds they have burned with fire, and the men of war are affrighted.

30Gbogbo àwọn jagunjagun Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn. Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin. Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun, gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́.

31Ìránṣẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn láti sọ fún ọba Babeli pé gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn.

32Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́ ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”

33Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí: “Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.”

34“Nebukadnessari ọba Babeli tó jẹ wá run, ó ti mú kí ìdààmú bá wa, ó ti sọ wá di àgbá òfìfo. Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì. Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó pọ̀ wá jáde.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.