8Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
9Ó ti bọ́ ògo mi, ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
10Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo, ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi, ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
12Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́n sì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.