9Ó ti bọ́ ògo mi, ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
10Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo, ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi, ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
12Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́n sì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.
13“Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.