Jobu 22

“Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà; nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.

Job 22:21 (UKJV) Acquaint now yourself with him, and be at peace: thereby good shall come unto you.

19Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀, àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé,

20‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò, iná yóò sì jó oró wọn run.’

21“Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà; nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.

22Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá, kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.

23Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró. Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.