13Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
14Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.
15Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.
16“Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀; ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.
17Òru gún mi nínú egungun mi, èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.