14Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.
15Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.
16“Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀; ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.
17Òru gún mi nínú egungun mi, èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.
18Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi, ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.