Jobu 30

Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi, ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.

Job 30:18 (UKJV) By the great force of my disease is my garment changed: it binds me about as the collar of my coat.

16“Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀; ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.

17Òru gún mi nínú egungun mi, èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.

18Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi, ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.

19Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀, èmi sì dàbí eruku àti eérú.

20“Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn; èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.