27Ikùn mí n ru kò sì sinmi, ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.
28Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn; èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.
29Èmi ti di arákùnrin ìkookò, èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.
30Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi; egungun mi sì jórun fún ooru.
31Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀, àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sọkún.