8ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.
9“Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
10kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
11Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀.
12Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.