7Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,
8ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.
9“Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
10kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
11Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀.