Jobu 34

“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.

Job 34:21 (UKJV) For his eyes are upon the ways of man, and he sees all his activities.

19mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ, nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?

20Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú, àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ; a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.

21“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.

22Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.

23Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.