25nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn, ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
26Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i,
27nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i, wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,
28kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní.
29Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi? Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i? Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;