23Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.
24Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí, a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn,
25nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn, ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
26Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i,
27nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i, wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,