33Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà? Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́, ìwọ gbọdọ̀ yan, kì í ṣe èmi. Nítorí náà sọ ohun tí o mọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ́!
34“Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi, àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,
35‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’
36Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin, nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú.
37Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa, ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”