34“Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi, àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,
35‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’
36Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin, nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú.
37Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa, ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”