Jobu 35

Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.

Job 35:12 (UKJV) There they cry, but none gives answer, because of the pride of evil men.

10Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;

11tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’

12Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.

13Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán; bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.

14Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ, ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.