12Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́, wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.
13“Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.
14Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe, ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
15Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn, a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.
16“Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀, ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.