10Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.
11Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín, wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn, àti ọdún wọn nínú afẹ́.
12Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́, wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.
13“Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.
14Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe, ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.