Jobu 36

Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́; àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

Job 36:7 (UKJV) He withdraws not his eyes from the righteous: but with kings are they on the throne; yea, he does establish them for ever, and they are exalted.

5“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.

6Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí, ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.

7Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́; àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

8Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

9nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.