Jobu 6

Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀, àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí: nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

Job 6:10 (UKJV) Then should I yet have comfort; yea, I would harden myself in sorrow: let him not spare; for I have not concealed the words of the Holy One.

8“Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà; àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.

9Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run, tí òun ìbá jẹ́ ṣíwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.

10Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀, àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí: nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

11“Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí? Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?

12Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí? Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.