10Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀, àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí: nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.
11“Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí? Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?
12Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí? Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?
13Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi: ọgbọ́n kò ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?
14“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá, kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?